Who cast that first fateful tomato that started the La Tomatina revolution? The reality is no one knows. Maybe it was an anti-Franco rebellion, or a carnival that got out of hand. According to the most popular version of the story, during the 1945 festival of Los Gigantes (a giant paper mâché puppet parade), locals were looking to stage a brawl to get some attention. They happened upon a vegetable cart nearby and started hurling ripe tomatoes. Innocent onlookers got involved until the scene escalated into a massive melee of flying fruit. The instigators had to repay the tomato vendors, but that didn't stop the recurrence of more tomato fights—and the birth of a new tradition.
Fearful of an unruly escalation, authorities enacted, relaxed, and then reinstated a series of bans in the 1950s. In 1951, locals who defied the law were imprisoned until public outcry called for their release. The most famous effrontery to the tomato bans happened in 1957 when proponents held a mock tomato funeral complete with a coffin and procession. After 1957, the local government decided to roll with the punches, set a few rules in place, and embraced the wacky tradition.
Though the tomatoes take center stage, a week of festivities lead up to the final showdown. It's a celebration of Buñol's patron saints, the Virgin Mary and St. Louis Bertrand, with street parades, music, and fireworks in joyous Spanish fashion. To build up your strength for the impending brawl, an epic paella is served on the eve of the battle, showcasing an iconic Valencian dish of rice, seafood, saffron, and olive oil.
Today, this unfettered festival has some measure of order. Organizers have gone so far as to cultivate a special variety of unpalatable tomatoes just for the annual event. Festivities kick off around 10 a.m. when participants race to grab a ham fixed atop a greasy pole. Onlookers hose the scramblers with water while singing and dancing in the streets. When the church bell strikes noon, trucks packed with tomatoes roll into town, while chants of "To-ma-te, to-ma-te!" reach a crescendo.
Then, with the firing of a water cannon, the main event begins. That's the green light for crushing and launching tomatoes in all-out attacks against fellow participants. Long distance tomato lobbers, point-blank assassins, and medium range hook shots. Whatever your technique, by the time it's over, you will look (and feel) quite different. Nearly an hour later, tomato-soaked bombers are left to play in a sea of squishy street salsa with little left resembling a tomato to be found. A second cannon shot signals the end of the battle. | Taani çni tí ó ju tòmátì àkökö èyí tí ó bêrê àsà tòmátì jíjù mö ara çni? Òtítö ibê ni wí pe kò sí çni tí ó leè sô. Bóyá ó leè jë ìdìtê tako êyà faransé tàbí ayçyç kan tí apá ò ká mö ni. Gëgë bí ìtàn kan tí ó gbajú gbajà tí a gbö se wí, ní àkókò ôdún Losi Gìgántçsì ní ôdún 1945 (ní ibi tí wön tí máa ngbé òmìrán dômí tí wön fi tákàdá tí wön gún põ se yí ká ìlú), àwôn ômô ìbílê nwá õnà bí wön se leè pàtç rògbòdìyàn láàrin ìgboro kí wön leè fi polongo ara wôn. Lójijì ni wön bö sí orí ômôlanke kan tí ó wà ní ìtòsí, wön sì bêrê sí ní ju tòmátì tí ó ti pön mö ara wôn. Àwôn olùwòran tí wôn ò môwö-mçsê náà fi ara gbá ní bê títí tí õrõ náà fi di bí oò lô yà fún mi, tí gbogbo èèyàn sìí nsáré sókè-sódò nígbàtí èso tòmátì nfò kiri síhïn-sóhün. Àwôn tí wön bêrê õràn yí ní láti san owó fún onítòmátì náà, sùgbön èyí kò dá a dúró pé kí ìsêlê ìjà tòmátì ó má tún sçlê mö- bëêni kò se ìdádúró fún bíbí àsà tuntun. Ní ìbêrù pé kí àsà yìí má baà peléke sí i, àwôn alásç se òfin lákºkò kan, wön tún dç ôwö díê lára òfin náà, lëhìn náà wön tún se onírúurú òfin láti gbësê lé irú àsàkásá bëê, ìyçn ní ààrin ôdún 1950 sí 1959. Ní ôdún 1951, àwôn ômô ìbílê tí wön rú òfin yì í ni wön fi êwõn jura títí di ìgbà tí àwôn ará ìlu se ìwóde ìfêhónúhàn láti pè fún ìtúsílê wôn. Ìgbésê akin tí ó gbajú gbajà jùlô láti gbësê lé àsà tòmátì jíjù mö ara çni ni èyí tí ó wáyé ní ôdún 1957 nígbàtí àwôn tí ó se agbáteru òfin náà se ètò ìsìnkú çlëyà fún tòmátì pêlú pósí kan, tí wön sì tò löwõõwö. Lëhìn ôdún 1957, ìjôba ìbílê pinnu láti wá gbogbo õnà láti wá ojútü sí ìsòro yìí, wön gbé òfin bíi mélòó kan kalê, wá fi ôgbön fi ara mö àsà ríndinríndin yìí. Bíótilêjêwìpè tòmátì ni wön fi orí àjõdún yìí sô, onírúurú ètò ayõ-ôdún tí ó gba õsê kan gbáko wön ni won npiyamô títí di ôjö àsèkágbá jàgídíjàgan náà. Èyí jë ayçyç àyësí fún pátríónì mímö ti Bùnólì, Maria mímö àti Lúwìsì Bátírándì mímö, pêlú ìyankálü, orin, àti títan iná alárànbarà lönà tí ó bá àsà Sípánìshì mu. Láti gbaradì fún rògbòdìyàn tí ó seése kí ó sçlê, oúnjç ìsênbáyé tí wôn þpé ni pàëlà, órisìí oúnjç kan tí ó wöpõ ní agbègbè Fàlënsìà tí wôn fi ìrçsì, çran, çja àti ewébê pèse rê, ni wôn nhá fún àwôn akópa láti jç ní ôjö tí ayçyç onírògbòdìyàn yìí bá ku õla. Lónìí, ôdún yï tí kò ti ní ijànu tëlê rí ti wà létòlétò báyìí. Àwôn tí nse ètò ayçyç yìí ti wá sé débi pé wön ngbin onírúurú tòmátì tí kò seé jç fún ayçyç ôlödôôdún yìí lásán. Ayçyç nbêrê ní déédé aago mëwàá òwúrõ nígbàtí àwôn akópa yóò máa sáré láti gbá çsê çlëdê tí wön so mö ara òpó kan tí nyõ mú. Àwôn olùwòran á máa tç omi sí wôn lára bí wön se nlàkàkà láti gun òpó yì í, tí wön si nkôrin, tí wön njó lójú pópó. Nígbàtí aago söõsì bá lu ti õsán, àwôn ôkõ akërù tí ó kún fún tòmátì á wõlú, bëê ni ariwo “Tò-má-tì, tò-má-tì” á gba gbogbo agbègbè kan. Lëyìn èyí pêlú yínyin ìbôn olómi, ojúlówó ayçyç bêrê ní pçrçwu. Èyí ni ìbêrê fífö àti jíju tòmátì mô ara çni. Àwôn tí ó jë pé láti òkèèrè ni wön ti nju tòmátì ti wôn, àwôn tí wön ní çni tí wön fi ti wôn sùn, àti àwôn tí wôn kò jìnnà púpõ sí ojú agbo, gbogbo wôn náà ni wön sáà nju tòmátì bí wön se fë. Èyíkéyìí õnà tí o leè gbà máa jù ú, nígbàtí yóò bá fi di òpin ohun gbogbo, wàá wo ara rç (ó sì mö lára) pé o ti yàtõ. Lëyìn nkan bí wákàtí kan ó dín díê, ó ku kí àwôn tí omi tòmátì ti mù dùndùndùn máa seré nínú agbami tòmátì tí ó ti rõ dòmù-dòmù tí ó kún lê, tí ò tiê sì jô tòmátì mö. Yínyín ìbôn lëêkejì ni ó nse àmìn òpin ìjàgbùdù náà. |